20 Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ,a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju;a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́,láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà.
21 Ṣé ẹ kò tíì mọ̀?Ẹ kò sì tíì gbọ́?Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀,kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé:
22 Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé,àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀.Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa,ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀.
23 Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀,ó sọ àwọn olóyè ayé di asán.
24 Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n,wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀;nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,tí wọ́n fi rọ bí ewéko,tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko.
25 Ta ni ẹ óo wá fi mí wé,tí n óo sì dàbí rẹ̀?Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀.
26 Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run,ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi?Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun,tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan,tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀.Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó,ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó,ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì.