23 Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀,ó sọ àwọn olóyè ayé di asán.
24 Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n,wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀;nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,tí wọ́n fi rọ bí ewéko,tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko.
25 Ta ni ẹ óo wá fi mí wé,tí n óo sì dàbí rẹ̀?Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀.
26 Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run,ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi?Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun,tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan,tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀.Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó,ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó,ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì.
27 Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́?Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé,“OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí,Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.”
28 Ṣé o kò tíì mọ̀,o kò sì tíì gbọ́pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA,Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.Àwámárìídìí ni òye rẹ̀.
29 A máa fún aláàárẹ̀ ní okun.A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára.