28 Ṣé o kò tíì mọ̀,o kò sì tíì gbọ́pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA,Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.Àwámárìídìí ni òye rẹ̀.
29 A máa fún aláàárẹ̀ ní okun.A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára.
30 Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn,àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata.
31 Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWAyóo máa gba agbára kún agbára.Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì.Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn;wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.