3 Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé,“Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù,ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀.
4 Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè,a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀:Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́,ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú.
5 Ògo OLUWA yóo farahàn,gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i.OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.”
6 Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”Mo bá bèèrè pé,“Igbe kí ni kí n ké?”Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá.
7 Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.Dájúdájú koríko ni eniyan.
8 Koríko a máa rọ,òdòdó a sì máa rẹ̀;ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.”
9 Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni,kí o máa kéde ìyìn rere.Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu,ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rereké sókè má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlú Juda pé,“Ẹ wo Ọlọrun yín.”