1 “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù,kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn,kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn,ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́.
2 “Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn?Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀?Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀?Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku,ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko.
3 A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí.
4 Ta ló ṣe èyí?Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.
5 “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé.