10 Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró.
11 “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ runni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,wọn óo sì ṣègbé.
12 O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,o kò ní rí wọn.Àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóo di òfo patapata.
13 Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,èmi ni mo sọ fún ọ pékí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.”
14 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,ẹ̀yin ọmọ Israẹli,OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.
15 Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun,tí ó mú, tí ó sì ní eyín,ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú;ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù.
16 Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ,ìjì yóo sì fọ́n wọn ká.Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWAẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.