21 OLUWA, Ọba Jakọbu, ní:“Ẹ̀yin oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ ro ẹjọ́ yín,kí ẹ mú ẹ̀rí tí ó dájú wá lórí ohun tí ẹ bá ní sọ.
22 Ẹ mú wọn wá,kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa;kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa.Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò;kí á lè mọ àyọrísí wọn,tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”
23 OLUWA ní, “Ẹ sọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la fún wa,kí á lè mọ̀ pé oriṣa ni yín;ẹ ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú kan,kí á rí i, kí ẹ̀rù sì bà wá.
24 Ẹ wò ó! Òfo ni yín, òfo sì ni iṣẹ́ ọwọ́ yín,ẹni ìríra ni ẹni tí ó bá yàn yín.
25 Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá,ó sì ti dé.Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi;yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó,àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀.
26 Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀,ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀;ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
27 Èmi OLUWA ni mo ti kọ́kọ́ sọ fún Sioni,tí mo sì ròyìn ayọ̀ náà fún Jerusalẹmu.