3 A máa lépa wọn, a sì máa kọjá wọn láìléwu,ní ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tẹ̀ rí.
4 Ta ló ṣe èyí?Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni?Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.
5 “Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù bà wọ́n,gbogbo òpin ayé gbọ̀n rìrì wọ́n ti súnmọ́ tòsí, wọ́n ti dé.
6 Olukuluku ń ran ẹnìkejì rẹ̀ lọ́wọ́,ó ń sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ṣara gírí.’
7 Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjúẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ,Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’Wọ́n kàn án ní ìṣó,ó le dáradára, kò le mì.
8 “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi,Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn,ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.
9 Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé,tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ,mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́,mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’