8 “Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi,Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn,ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.
9 Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé,tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ,mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́,mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’
10 Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ,má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ.N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́;ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró.
11 “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ runni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú.Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán,wọn óo sì ṣègbé.
12 O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì,o kò ní rí wọn.Àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóo di òfo patapata.
13 Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ,ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,èmi ni mo sọ fún ọ pékí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.”
14 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán,ẹ̀yin ọmọ Israẹli,OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín.