1 Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu,gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí,Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ.Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada;mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.
2 Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá,n óo wà pẹlu rẹ;nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá,kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀,nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ.Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.
3 Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ.Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada,mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ.
4 Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ,mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ;mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.
5 Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ,n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.