21 Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,kí wọ́n lè kéde ògo mi.
22 “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
23 Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi,tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi.N kò fi tipátipá mu yín rúbọ,bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá.
24 Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi,tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn.Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu,ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín.
25 Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,nítorí ti ara mi;n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.
26 “Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn;ẹ ro ẹjọ́ tiyín,kí á lè da yín láre.
27 Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀,àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí.