24 Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi,tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn.Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu,ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín.
25 Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,nítorí ti ara mi;n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.
26 “Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn;ẹ ro ẹjọ́ tiyín,kí á lè da yín láre.
27 Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀,àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí.
28 Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun;mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”