4 Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ,mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ;mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.
5 Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ,n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
6 N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé,‘Dá wọn sílẹ̀.’N óo sọ fún ìhà gúsù pé,‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè,sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé,
7 gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè,àwọn tí mo dá fún ògo mi,àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”
8 Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde,àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́,wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.
9 Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ,kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀.Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí,tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá;kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́,kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”
10 OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn;kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́,kí ó sì ye yín pé, Èmi ni.A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi,òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.