1 OLUWA ní:“Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ miẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi.
2 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.
3 “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹn óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,
4 wọn óo rúwé bíi koríko inú omiàní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn.