Aisaya 44:17-23 BM

17 Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”

18 Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn.

19 Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?”

20 Kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń pe eérú ní oúnjẹ. Èrò ẹ̀tàn ti ṣì í lọ́nà, kò sì lè gba ara rẹ̀ kalẹ̀ tabi kí ó bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ irọ́ kọ́ ni ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi yìí?”

21 Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi,nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli.Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́,n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli.

22 Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma,mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu.Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada.

23 Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é.Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀.Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀,nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada,yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli.