2 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.
3 “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹn óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,
4 wọn óo rúwé bíi koríko inú omiàní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn.
5 “Ẹnìkan yóo wí pé,‘OLUWA ló ni mí.’Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu.Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.”
6 Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.
7 Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi.Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa.
8 Má bẹ̀rù, má sì fòyà.Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́,mo ti kéde rẹ̀,ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi:Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi?Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”