6 Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.
7 Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi.Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa.
8 Má bẹ̀rù, má sì fòyà.Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́,mo ti kéde rẹ̀,ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi:Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi?Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”
9 Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n.
10 Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè?
11 Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀.
12 Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́.