1 Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí:Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò,láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀,láti tú àmùrè àwọn ọba,láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀,kí ẹnubodè má lè tì.
2 OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ,n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀;n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin.
3 N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn,ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀;kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli,ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.
4 Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi,ati Israẹli, àyànfẹ́ mi,mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí.
5 “Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn,kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí.
6 Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.
7 Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn,èmi ni mo dá alaafia ati àjálù:Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.