2 Gbé ọlọ kí o máa lọ ọkà,ṣí aṣọ ìbòjú rẹ kúrò,ká aṣọ rẹ sókè, kí o ṣí ẹsẹ̀ rẹ sílẹ̀,kí o sì la odò kọjá.
3 A óo tú ọ sí ìhòòhò,a óo sì rí ìtìjú rẹ.N óo gbẹ̀san,n kò sì ní dá ẹnìkan kan sí.
4 Olùràpadà wa, tí ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
5 OLUWA wí nípa Kalidea pé:“Jókòó kí o dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì wọ inú òkùnkùn lọ,ìwọ ọmọbinrin Kalidea.Nítorí a kò ní pè ọ́ ní ayaba àwọn orílẹ̀-èdè mọ́.
6 Inú bí mi sí àwọn eniyan mi,mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra.Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,o kò ṣàánú wọn.O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn.
7 O sọ pé ìwọ ni o óo máa jẹ́ ayaba títí lae,nítorí náà o kò kó àwọn nǹkan wọnyi lékàn,o kò sì ranti ìgbẹ̀yìn wọn.
8 “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé,tí o jókòó láìléwu,tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé,‘Èmi nìkan ni mo wà,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.N kò ní di opó,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’