Aisaya 47:8-14 BM

8 “Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé,tí o jókòó láìléwu,tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé,‘Èmi nìkan ni mo wà,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.N kò ní di opó,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’

9 Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì,lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó,ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́,kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ.

10 “Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ,o ní ẹnìkan kò rí ọ.Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà,ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà.Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’

11 Ṣugbọn ibi yóo dé bá ọ,tí o kò ní lè dáwọ́ rẹ̀ dúró;àjálù yóo dé bá ọ,tí o kò ní lè ṣe ètùtù rẹ̀;ìparun yóo dé bá ọ lójijì,tí o kò ní mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

12 Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ,sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ,tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré,bóyá o óo tilẹ̀ yege,tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan.

13 Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ;jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí,àwọn tí ó ń wojú ọ̀run,ati àwọn awòràwọ̀;tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ,nígbà tí oṣù bá ti lé.

14 “Wò ó! Wọ́n dàbí àgékù koríko,iná ni yóo jó wọn ráúráú,wọn kò sì ní lè gba ara wọn kalẹ̀, ninu ọ̀wọ́ iná.Eléyìí kì í ṣe iná tí eniyan ń yá,kì í ṣe iná tí eniyan lè jókòó níwájú rẹ̀.