19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn,arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà.Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé,bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.”
20 Ẹ jáde kúrò ní Babiloni,ẹ sá kúrò ní Kalidea,ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀,ẹ kéde rẹ̀,ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé“OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.”
21 Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n,nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá,ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta,ó la àpáta, omi sì tú jáde.
22 OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”