4 Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín,olóríkunkun sì ni yín pẹlu.
5 Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́:kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín,kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n,àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’
6 “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́,nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀?Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.
7 Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn,ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní.Kí ẹ má baà wí pé:Wò ó, a mọ̀ wọ́n.
8 Ẹ kò gbọ́ ọ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí,nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè,ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀,láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.
9 “Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi,nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín,kí n má baà pa yín run.
10 Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́,ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka,mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú.