1 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun.Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè,láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí,láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi.
2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú,ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀,ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú,ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀.
3 Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli,àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.”
4 Ṣugbọn mo dáhùn pé,“Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù.Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù,sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.”Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi.
5 Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún,kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá,ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA,Ọlọrun mi sì ti di agbára mi.
6 OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun,láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ.Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdèkí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.
7 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ,fún ẹni tí ayé ń gàn,tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra,iranṣẹ àwọn aláṣẹ,ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde,àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀.Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo,Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”