Aisaya 49:5-11 BM

5 Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún,kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá,ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA,Ọlọrun mi sì ti di agbára mi.

6 OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun,láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ.Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdèkí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.

7 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ,fún ẹni tí ayé ń gàn,tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra,iranṣẹ àwọn aláṣẹ,ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde,àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀.Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo,Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”

8 OLUWA ní,“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn,lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.Mo ti pa ọ́ mọ́,mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé,láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀,láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro.

9 Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà,gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn.

10 Ebi kò ní pa wọ́n,òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n,atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n,nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn,yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.

11 “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà,n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi.