3 Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi.
4 Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,kí ló dé tí ó fi so èso kíkan?
5 Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín.N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká,iná yóo sì jó o.N óo wó odi tí mo mọ yí i ká,wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
6 N óo jẹ́ kí ó di igbó,ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́,wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́.Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀.N óo pàṣẹ fún òjòkí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́.
7 Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;ó ń retí ìwà òdodo,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.
8 Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé,tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀,títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́,kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà.
9 OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé.