1 “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA,ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín,ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde.
2 Ẹ wo Abrahamu baba yín,ati Sara tí ó bi yín.Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é,tí mo súre fún un,tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan.
3 “OLUWA yóo tu Sioni ninu,yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu;yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA.Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀,pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.
4 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde,ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan.
5 Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí,ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀.Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan,àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi,ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí.