11 Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá,pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni.Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí,wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn;ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.
12 “Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu,ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú?Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko.
13 O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ,tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára,nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run?Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́.
14 Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀.Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú,wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì.
15 “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,ẹni tí ó rú òkun sókè,tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi.
16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”
17 Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu.Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,tí ojú rẹ wá ń pòòyì.