14 Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀.Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú,wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì.
15 “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,ẹni tí ó rú òkun sókè,tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi.
16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”
17 Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu.Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,tí ojú rẹ wá ń pòòyì.
18 Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà,ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí,kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́,ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà.
19 Àjálù meji ló dé bá ọ,ta ni yóo tù ọ́ ninu:Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun,ta ni yóo tù ọ́ ninu?
20 Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ,wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó,bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n.Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí,àní ìbáwí Ọlọrun rẹ.