12 Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.
13 Wò ó! Iranṣẹ mi yóo ṣe àṣeyọría óo gbé e ga, a óo gbé e lékè;yóo sì di ẹni gíga,
14 Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rẹ̀.Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna,tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́.
15 Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu,nígbà tí wọ́n bá rí i,wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀,òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.