10 Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò,tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
11 OLUWA ní:“Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá,tí a kò sì tù ninu,òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ,òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.
12 Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ,òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.
13 “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.
14 A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.
15 Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an,ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.”
16 OLUWA ní,“Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ,tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná,tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀,èmi náà ni mo dá apanirun,pé kí ó máa panirun.