4 Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́,má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́,nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ,o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́.
5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ,OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ,Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.
6 Nítorí OLUWA ti pè ọ́,bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́,àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀;OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
7 Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú.
8 Mo fojú mi pamọ́ fún ọ,fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ,ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ.Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9 Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi:mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii,pé n kò ní bínú sí ọ mọ́,pé n kò ní bá ọ wí mọ́.
10 Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò,tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.