Aisaya 58:2-8 BM

2 Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ,wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi,wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo,tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀.Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi,wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.”

3 Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa?Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?”OLUWA wí pé,“Ìdí rẹ̀ ni pé,nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín.Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára.

4 Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.

5 Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?

6 “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:kí á tú ìdè ìwà burúkú,kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,kí á já gbogbo àjàgà?

7 Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.

8 “Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́,ara yín yóo sì tètè yá.Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín.Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín.