Aisaya 58:4-10 BM

4 Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.

5 Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?

6 “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:kí á tú ìdè ìwà burúkú,kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,kí á já gbogbo àjàgà?

7 Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.

8 “Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́,ara yín yóo sì tètè yá.Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín.Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín.

9 Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,n óo sì da yín lóhùn.Ẹ óo kígbe pè mí,n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’“Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín,tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́,tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́.

10 Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ,ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn,òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán.