2 Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò.
3 Ekinni ń ké sí ekeji pé:“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun;gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
4 Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà.
5 Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.”
6 Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi.
7 Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
8 Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?”Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”