4 Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà.
5 Mo bá pariwo, mo ní, “Mo gbé! Mo ti sọnù, nítorí pé ọ̀rọ̀ ẹnu mi kò mọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tí mò ń gbé ààrin wọn náà kò sì mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni mo ti fi ojú rí Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun.”
6 Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi.
7 Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
8 Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?”Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”
9 OLUWA bá ní:“Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé;wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn;wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan.
10 Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì,jẹ́ kí etí wọn di.Fi nǹkan bò wọ́n lójú,kí wọn má baà ríran,kí wọn má sì gbọ́ràn,kí òye má baà yé wọn,kí wọn má baà yipada,kí wọn sì rí ìwòsàn.”