6 Ọ̀kan ninu àwọn Serafu náà bá fi ẹ̀mú mú ẹ̀yinná kan lórí pẹpẹ, ó mú un lọ́wọ́, ó bá fò wá sọ́dọ̀ mi.
7 Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
8 Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?”Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”
9 OLUWA bá ní:“Lọ, sọ fún àwọn eniyan wọnyi pé;wọn óo gbọ́ títí, ṣugbọn kò ní yé wọn;wọn óo wò títí, ṣugbọn wọn kò ní rí nǹkankan.
10 Mú kí ọkàn àwọn eniyan wọnyi ó yigbì,jẹ́ kí etí wọn di.Fi nǹkan bò wọ́n lójú,kí wọn má baà ríran,kí wọn má sì gbọ́ràn,kí òye má baà yé wọn,kí wọn má baà yipada,kí wọn sì rí ìwòsàn.”
11 Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?”Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata.
12 Tí OLUWA yóo kó àwọn eniyan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tí ibi tí a kọ̀tì yóo sì di pupọ ní ilẹ̀ náà.