1 Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.
2 Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀,òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ,ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ.
3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ,àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn.
4 Gbé ojú sókè kí o wò yíká,gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè,a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá.
5 Nígbà tí o bá rí wọn,inú rẹ yóo dùn,ara rẹ óo yá gágá.Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀,nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.