Aisaya 60:14-20 BM

14 Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá,wọn óo tẹríba fún ọ;gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,wọ́n sì kórìíra rẹ,tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.

16 O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,o óo mu wàrà àwọn ọba.O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ,ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.

17 “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo.

18 Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́,kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ,o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà,o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn.

19 “Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru:OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ.

20 Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn.Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin.