Aisaya 60:5-11 BM

5 Nígbà tí o bá rí wọn,inú rẹ yóo dùn,ara rẹ óo yá gágá.Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀,nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.

6 Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká,àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa.Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá,wọn óo mú wúrà ati turari wá;wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA.

7 Gbogbo ẹran ọ̀sìn Kedari ni wọ́n óo kó wá fún ọ,wọn óo kó àgbò Nebaiotu wá ta ọ́ lọ́rẹ.Wọn óo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi,ilé mi lógo, ṣugbọn n óo tún ṣe é lógo sí i.

8 Ta ni àwọn wọnyi tí ń fò lọ bí ìkùukùu?Bí ìgbà tí àwọn àdàbà bá ń fò lọ sí ibi ìtẹ́ wọn?

9 Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí,ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwajuwọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè,wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn;nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ,ati Ẹni Mímọ́ Israẹli,nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo.

10 OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ,àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ;nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́.Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ.

11 Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo,a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru;kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ,pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju.