1 Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́,nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi,títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀,tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà.
2 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ,gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ;orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́,ni a óo máa pè ọ́.
3 O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA,ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ.
4 A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́,“Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́,a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.”Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ,ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.
5 Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.