Aisaya 62:4-10 BM

4 A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́,“Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́,a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.”Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ,ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.

5 Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.

6 Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ;lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí,ẹ má dákẹ́.

7 Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi,títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀,títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé.

8 OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra,ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́,pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ,ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́;àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ,tí o ṣe wahala lé lórí mọ́.

9 Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́,wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA;àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀,ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi.

10 Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá,ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan.Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà,kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà.