9 Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́,wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA;àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀,ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi.
10 Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá,ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan.Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà,kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà.
11 Wò ó! OLUWA ti kéde títí dé òpin ayé.Ó ní, “Ẹ sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,‘Wò ó, olùgbàlà yín ti dé,èrè rẹ wà pẹlu rẹ̀,ẹ̀san rẹ sì wà níwájú rẹ̀.’ ”
12 A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”,“Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”.Wọn óo máa pè yín ní,“Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”;wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní,“Ìlú tí a kò patì”.