1 Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀,kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ;
2 bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú,tí iná sì ń mú kí omi hó.Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ,kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ!
3 Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù,tí ẹnikẹ́ni kò retí,o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ.
4 Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
5 Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́,àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn,o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀,a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́.Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà?
6 Gbogbo wa dàbí aláìmọ́,gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin.Gbogbo wa rọ bí ewé,àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn.