Aisaya 65:16-22 BM

16 Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà,yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́,ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà,orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra.Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé,a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.”

17 OLUWA ní,“Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun;a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́,tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn.

18 Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn,kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá.Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀,mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn.

19 N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu,inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi.A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́,ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.

20 Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́,àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́.Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún.Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún,a óo sọ pé ó kú ikú ègún.

21 Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀;wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀.

22 Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé,wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ.Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò,àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.