22 Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé,wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ.Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò,àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
23 Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù,wọn kò ní bímọ fún jamba;nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́,àwọn ati àwọn ọmọ wọn.
24 Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn,kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.
25 Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri;kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù,erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára.Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”