Aisaya 65:9-15 BM

9 N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu,àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda.Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀,àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀.

10 Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran,àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí,fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi.

11 “Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀,tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi,tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire,tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́.

12 N óo fi yín fún ogun pa,gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn;nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́,ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi;ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí.

13 Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ,ṣugbọn ebi yóo máa pa yín;àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini,ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín.Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀,ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín.

14 Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn,ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá;ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn.

15 Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ miyóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún.Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín.Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn.