8 Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.”
9 Ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ kó ara yín jọ!A óo fọ yín túútúú.Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè.Ẹ di ara yín ní àmùrè;a óo fọ yín túútúú.Ẹ di ara yín ní àmùrè,a óo fọ yín túútúú.
10 Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo.Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán.Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa.
11 Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní,
12 “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù.
13 OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà.
14 Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu.