18 Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.
19 Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná,àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu ináẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.
20 Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́,sibẹ ebi ń pa wọ́n.Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì,sibẹ wọn kò yó,àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ.
21 Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà.Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.