24 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní,“Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí;ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ.
25 Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi;n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi,ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí.
26 Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí,mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.”
27 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu;ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣeta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?
28 Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:
29 Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.
30 Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ,aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu.Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ,a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.