3 Ìlú olódi kò ní sí mọ́ ní Efuraimu,kò sì ní sí ìjọba mọ́ ní Damasku,àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Siriayóo sì dàbí ògo àwọn ọmọ Israẹli,OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.
4 “Tó bá di ìgbà náà,a óo rẹ ògo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀,ọrọ̀ wọn yóo di àìní.
5 Yóo dàbí ìgbà tí eniyan kórè ọkà lóko,tí ó kó ṣiiri ọkà kún apá.Tí àwọn kan tún wá ṣa ọkà yòókù,tí àwọn tí wọn kọ́ kórè ọkà gbàgbé ní àfonífojì Refaimu.
6 Àṣàkù yóo kù níbẹ̀,bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi,yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi,tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.”OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.
7 Tó bá di ìgbà náà, àwọn eniyan yóo bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóo sì máa wo ojú Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8 Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari.
9 Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.